Oro lo ji tuu, lo na’wo lalaala
Bi eyi ti yoo fi gun Olorun loju
Bee n o lee fi gun Olorun loju
Ija Orisa ni won n gbe
Dia fun Ose-Teere
Tii se Ituko Olodumare
Ebo ni won ni ko waa se
O gbebo, o rubo
Aje, aya, omo, ile, ire gbogbo ile yii nko o?
T’ose–Teere ni o
Iwo ni Ituko Olodumare
Paakara woo-woo-woo Awo idi Esu
Dia fun Ose-Teere
Ti n gb’ebo ilee r’ode Orun
Ebo ni won ni ko waa se
O gb’ebo, o ru’bo
Eni f’owo o ni
E waa ran’fa nise
Ose ngb’ebo o r’ode orun
Bi e nise e ran
Sosoro Awo abata
Dia fun Oloriire Apesin
Sosoro o de o, Awo Apesin
Eyin o mo wipe
Oloriire laa pee sin
Penpe lapa eye fi nju itan eye lo
Dia fun Ori, omo Atete-niran
Omo Atete gbeni ku f’oosa
Owo ti mo ni lonii
Orii mi ma ni o
Opelope Otura-Oriko
Obara Owonrin oni’pon oje
Agbara bi agogo ide
Dia fun Orunmila
Ti tiku-tarun nkan’le ree pe
Ajogun Iku kan’le ree lo
Won ni o ka’ra nle ebo ni sise
O gb’ebo, o ru’bo
Obara monamona awo Oloyannbere
Dia fun Oloyannbere
Eyi ti nloo d’onile l’ese oke
Ebo ni won ni ko se
O gb’ebo, o ru’bo
Mo wa d’onile l’ese oke
Gunnugun awo ile Onikamogun
Dia fun Onikamogun
Won ni ko rubo nitori Aje
Akala lawo ile Onikamogun
Dia fun Onikamogun
Won ni ko rubo nitori Aya
Mo ta kua
Awo Igun lo dia fun Igun
Ororo mode awo Aparo
Dia fun Aparo
Aranrapongba awo Arira
Dia fun Arira
Ope ja suuru kanle
Dia fun Orunmila
To ji l’owuro kutukutu
Ti nsunkun oju oun o kan’re
Ebo ni won ni ko waa se
O gb’ebo, O ru’bo
Otura funfun Sese
Dia fun Lekeleke
Ti nraye awure
Ebo ni won ni ko waa se
O gb’ebo, o ru’bo
Ase.
Ki ona rere sile yi maa si.
Ki ire aje, ire omo, ire aiku, ire alaafia maa bo.
Ki gbogbo ohun rere maa dagba lori OracleIfa.
Ki oro buburu maa jina.
Ki Ori rere maa dari ise yi.
Ase.
Gunnugun awo ile Onikamogun
Dia fun Onikamogun
Won ni ko rubo nitori Aje
Akala lawo ile Onikamogun
Dia fun Onikamogun
Won ni ko rubo nitori Aya
Asawo-sagbe e ko loko awo ile Onikamogun
Dia fun Onikamogun
Won ni ko rubo nitori Ogun
Ifa ma se o
Asawo-sagbe Ifa ma se o